Ezekiel 21:2-11

2“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jerusalẹmu, kí o sì wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ̀ Israẹli. 3Kí ó sì sọ fún un pe: ‘Èyí yìí ni Olúwa wí: Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárín yín. 4Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúúsù títí dé àríwá. 5Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’

6“Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn. 7Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mí ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa Olódùmarè wí.”

8Ọ̀rọ̀ Olúwa si tún tọ̀ mí wá pé: 9“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní Olúwa wí pé:

“ ‘Idà kan, Idà kan,
tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú,
10a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀,
a dán an láti máa kọ mọ̀nà!
“ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀.

11“ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n,
kí ó lè ṣe é gbámú;
a pọ́n ọn, a sì dán an,
ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.
Copyright information for YorBMYO